15Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.
16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi, àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.