30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.
33Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan.
34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.