1Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera, ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
3Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.
4Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.