16Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.
18Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20Wọ́n pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.