Saamu 107

àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá.

Psalm 107:3 (UKJV) And gathered them out of the lands, from the east, and from the west, from the north, and from the south.

1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

2Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

3àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá.

4Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé.

5Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.