5Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
6Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.
8Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú; kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.
9Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba kí aya rẹ̀ sì di opó.