7Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.
8Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú; kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.
9Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba kí aya rẹ̀ sì di opó.
10Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.
11Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.