145Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn Olúwa, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.