10Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.