7Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti, àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani: