Saamu 25

Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

Psalm 25:13 (UKJV) His soul shall dwell at ease; and his seed shall inherit the earth.

11Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.

12Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

13Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

14Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.

15Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.