Saamu 25

Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.

Psalm 25:18 (UKJV) Look upon mine affliction and my pain; and forgive all my sins.

16Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.

17Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.

18Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.

19Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

20Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.