9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa, àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
11Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde; wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.
13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;