5Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi.
6Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
7Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.
8Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
9Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.