Saamu 38

Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

Psalm 38:9 (UKJV) Lord, all my desire is before you; and my groaning is not hid from you.

7Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.

8Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.

11Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.