Saamu 38

Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Psalm 38:8 (UKJV) I am feeble and sore broken: I have roared by reason of the chaos of my heart.

6Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.

8Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.