Saamu 4

Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

Psalm 4:3 (UKJV) But know that the LORD has set apart him that is godly for himself: the LORD will hear when I call unto him.

1Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

2Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

3Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀, nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

5Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.