12Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
13Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.