Saamu 68

Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká; kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.

Psalm 68:1 (UKJV) Let God arise, let his enemies be scattered: let them also that hate him flee before him.

1Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká; kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.

2Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ, kí ó fẹ́ wọn lọ; bí ìda ti í yọ́ níwájú iná, kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.

3Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run; kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.