20Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani; èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ, àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
24Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run, ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.