Saamu 69

Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

Psalm 69:1 (UKJV) Save me, O God; for the waters are come in unto my soul.

1Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

2Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.