2Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo, yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kéékèèké nípa òdodo.
4Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5Àwọn òtòṣì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀, bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.