Saamu 73

Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

Psalm 73:18 (UKJV) Surely you did set them in slippery places: you casted them down into destruction.

16Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,

17títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

19Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!

20Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.