14Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
15Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
17títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
18Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.