21Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò,
22mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.
23Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.
25Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.