Saamu 78

Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.

Psalm 78:49 (UKJV) He cast upon them the fierceness of his anger, wrath, and indignation, and trouble, by sending evil angels among them.

47Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.

48Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.

49Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.

50Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀, òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.

51Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti, olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.