Saamu 78

Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.

Psalm 78:47 (UKJV) He destroyed their vines with hail, and their sycomore trees with frost.

45Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.

46Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú.

47Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.

48Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.

49Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.