Saamu 78

Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú.

Psalm 78:46 (UKJV) He gave also their increase unto the caterpillar, and their labour unto the locust.

44Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀; wọn kò lè mu láti odò wọn.

45Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.

46Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú.

47Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.

48Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.