69Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.