9Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa; ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ: ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.