38Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.
39Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo; ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.
40Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
41Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ; ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
42Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè; ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.