5Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
9Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.