3Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.