16Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú? Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
18Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
20Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?