Saamu 97

Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì.

Psalm 97:4 (UKJV) His lightnings enlightened the world: the earth saw, and trembled.

2Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.

4Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì.

5Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa, níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.