Ìfihàn 18

Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”

Revelation 18:3 (UKJV) For all nations have drunk of the wine of the wrath of her fornication, and the kings of the earth have committed fornication with her, and the merchants of the earth are waxed rich through the abundance of her delicacies.

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí angẹli mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀.

2Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú! Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù, àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo, àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo, ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo.

3Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”

4Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé: “ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’ kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.

5Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.