1Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.
2Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
3Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; ẹnu rẹ̀ dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ.