9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é.
10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀, o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí. “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.