Orin Solomoni 4

Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí.

Song of Solomon 4:6 (UKJV) Until the day break, and the shadows flee away, I will get me to the mountain of myrrh, and to the hill of frankincense.

4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

5Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.

6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí.

7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.