Sekariah 10

Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlùkù koríko ní pápá.

Zechariah 10:1 (UKJV) Ask all of you of the LORD rain in the time of the latter rain; so the LORD shall make bright clouds, and give them showers of rain, to every one grass in the field.

1Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlùkù koríko ní pápá.

2Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán, àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké, wọn sì tí rọ àlá èké; wọ́n ń tu ni nínú lásán, nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn, a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́-àgùntàn kò sí.

3“Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran, èmi o sì jẹ àwọn olórí ní yà nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀, ilé Juda wò, yóò sì fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.