9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè: síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà.
10Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria. Èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni; a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já, yóò sì bori rírú omi nínú Òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀, ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.
12Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa; wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,” ni Olúwa wí.