4Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni èèkàn àgọ́ tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.
5Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.
6“Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára, èmi o sì gba ilé Josẹfu là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù; nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ tiwọn
7Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.
8Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ; nítorí èmi tí rà wọ́n padà; wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.