20wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè láti ìjọba kan sí èkejì.
21Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí.
22“Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi; má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”
23Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.