1 Kronika 2

Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

1 Chronicles 2:3 (UKJV) The sons of Judah; Er, and Onan, and Shelah: which three were born unto him of the daughter of Shua the Canaanitess. And Er, the firstborn of Judah, was evil in the sight of the LORD; and he slew him.

1Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni,

2Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.

3Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

4Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.

5Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.