34Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní. Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha.
35Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.
36Attai sì jẹ́ baba fún Natani, Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,
37Sabadi ni baba Eflali, Eflali jẹ́ baba Obedi,
38Obedi sì ni baba Jehu, Jehu ni baba Asariah,