7Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8Àwọn ọmọ Etani: Asariah.
9Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
10Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
11Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,