Amosi 9

“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀. Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni Olúwa wí.

Amos 9:8 (UKJV) Behold, the eyes of the Lord GOD are upon the sinful kingdom, and I will destroy it from off the face of the earth; saving that I will not utterly destroy the house of Jacob, says the LORD.

6Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé, Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀.

7“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?” ni Olúwa wí. “Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori àti àwọn ará Aramu láti Kiri?

8“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀. Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni Olúwa wí.

9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Israẹli ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

10Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.