Esekiẹli 32

Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

Ezekiel 32:1 (UKJV) And it came to pass in the twelfth year, in the twelfth month, in the first day of the month, that the word of the LORD came unto me, saying,

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un: “ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà; ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.

3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.