Hosea 9

Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.

Hosea 9:4 (UKJV) They shall not offer wine offerings to the LORD, neither shall they be pleasing unto him: their sacrifices shall be unto them as the bread of mourners; all that eat thereof shall be polluted: for their bread for their soul shall not come into the house of the LORD.

2Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.

3Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.

4Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.

5Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?

6Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Ejibiti yóò kó wọn jọ, Memfisi yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.