Hosea 9

Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.

Hosea 9:3 (UKJV) They shall not dwell in the LORD's land; but Ephraim shall return to Egypt, and they shall eat unclean things in Assyria.

1Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.

2Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.

3Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.

4Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.

5Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.